Home > Ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn àgbà òṣèré Yorùbá > Kareem Adepoju

Kareem Adepoju

Ọdún tí wọ́n bẹ̀rẹ̀:N/A]

Ọ̀rọ̀ ṣókí: Mo ri wípé Ọlọ́run fún mi ní ẹ̀bùn. Ìgbà tí mo ti discover ẹ̀bùn yẹn ni ìgbà tí a ti wà ní primary school. Bàbá wa Oyin Adéjọbí, ó jẹ́ ọ̀gá wa. Wọ́n máa ń wá kọ́ wa ní eré ní sùkúù Ansarudeen. Ansarudeen máa ń kó àwọn ọmọ sùkúù jọ lọ́dún láti kọ́ eré ní ọ̀dọ̀ bàbá. Wọ́n á wá ṣe é fún ìjọ lọ́dún. Owó tí wọ́n bá pa níbẹ̀ ni wọ́n á fi san owó fún àwọn àlùfáà tí ó ń kọ́ wọn ní Arabic nígbà náà (ọjọ́ ìfọ̀rọ̀wérọ̀: August 27, 2020).

Trans: I thought I had a God-given talent. It was in my primary school days that this first became evident. Baba Oyin Adejobi was our leader and taught us acting at the Ansarudeen mission school. The school invited him every year to train a selected few. Those pupils, in turn, acted in plays they presented to the congregation. And the proceeds from those plays went towards remunerating clerics that taught us Arabic.

Ẹgbẹ́: Oyin Adejobi Group.